Saheed Balógun | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 5 Oṣù Kejì 1967 Kwara State, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Kwara State Polytechnic |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́1978–presentNotable workÒfin mósèOlólùfẹ́
Saheed Balógun ni wọ̣́n bí ní ọjọ́ Karùún oṣu Kejì ọdún 1967 (February 5, 1967) ní ìpínlẹ̀ Kwara. Ó jẹ́ gbajú-gbajà òṣèré orí-ìtàgé, olùgbéré jáde, adarí eré, àti olùṣe fíímù ilẹ̀ Nàìjíríà.
Wọ́n bí Saheed ní ìpínlẹ̀ Kwara tí ó jẹ́ (North Central Nigeria), ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Níbi tí ó ti kàwé alákọ̀ọ́ bẹ̀rẹ̀ , ìwé girama àti ilé ìwé gíga .[3] Ó kàwé jáde ní ilé-ẹ̀kọ́ 'Kwara State Polytechnic' tí wọ́n ti yí padà sí (Kwara State University).[4] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ ní ọdún 1978, nígbà tí ó kọ́kọ́ ṣe ètò rẹ̀ kan lórí ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán tí ó pè ní "Youth Today" lórí NTA.[5] Ó ṣe sinimá àgbéléwò rẹ̀ àkọ́kọ́ tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ 'City Girl' ní ọdún 1989, àmọ́ tí ó sì ti gbé ọ̀pọ̀ sinimá jáde tí ó sì tún ti ṣe adarí fún ọ̀pọ̀ eré orí-ìtàgé mìíràn rẹpẹtẹ.[6]
Ó fẹ́ ìyàwó rẹ̀ tí òun náà jẹ́ òṣèré orí ìtàgé ìyẹn Fathia Balogun ṣùgbọ́n wọ́n ti pínyà báyìí. Ó bí ọmọ ọkùnrin kan Khalid Balógun àti obìnrin kan Aliyah Balógun.[7]
|title=
(help)
|title=
(help)
|title=
(help)